Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 17:42:18
Eyi lo wa ninu lẹta kan ti aarẹ kọ si ile igbimọ aṣofin, Aarẹ Sẹnetọ Godswill Akpabio si ka fun gbogbo ọmọ ile igbimọ aṣofin lọjọbọ, ọjọ karun un oṣu keji ọdun 2025.
Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 18:37:55
Fọnran to jade lori ayelujara ṣafihan bi awọn akẹkọọ se n sa si abẹ tabili wọn lẹyin ti wọn gboro ibọn.
Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 14:26:35
Oṣojumikoro, Yahaya Mahi to ba akọroyin BBC sọrọ ni ina naa bẹrẹ ni ile kan to wa ni iwaju yara awọn akẹkọọ ko to di pe o tan mọ ile awọn akẹkọọ.
Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 13:21:48
Ajọ NiMET tun sọrọ pe ọwọ ojo yoo tunbọ pọ sii laarin oṣu karun un si ikẹfa ọdun 2025 lorilẹede Naijiria. O ni eyi yoo gbilẹ lawọn ilu to wa lẹsẹ odo lorilẹede Naijiria.
Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 11:40:12
Igbakeji agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin laarọ Ọjọru ọjo karun un oṣu Keji ọdun yii.
Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 12:41:10
Wọ́nyi ni àwọn kò ṣeé má gbọ̀ọ́ ìròyìn káàkiri àgbáyé
Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 10:37:07
Ọgbẹni Udochukwu Samuel Ejezie to jẹ baba awọn ọmọ naa sọ fun BBC pe iṣẹlẹ ọhun waye lẹyin ile iwosan fasiti ẹkọṣẹ iṣẹgun Nnamdi Azikwe niluu Nnenwi.
Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 08:53:59
Nigba ti gomina Ademola Adeleke n ba awọn ọmọ iluu Esa-oke sọrọ, o fi da wọn loju wi pe, ẹnikẹni to ba wa nidi Isẹlẹ naa yoo fimu ko ata ofin.
Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 06:50:47
Oṣu Kẹsan-an ọdun 2024 ni Kayode Egbetokun pe ọgọta ọdun looke eepẹ.
Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Èrèlè 2025 ní 16:28:05
Ní òpin ọ̀sẹ̀ ni ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tí Bisi Akande ṣe pẹ̀lú akọ̀ròyìn Edmund Obilo gba orí ayélujára níbi tí Akande ti sọ pé Ladoja nímọ̀ nípa àwọn nǹkankan lórí ikú Bola Ige.
Ọjọ́rú, 5 Oṣù Èrèlè 2025 ní 11:40:12
Igbakeji agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo fidi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin laarọ Ọjọru ọjo karun un oṣu Keji ọdun yii.
Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Èrèlè 2025 ní 12:50:20
Ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kìíní, ọdún 2023 ni àwọn ọ̀daràn náà lọ ká àwọn tọkọtaya náà mọ́lé lẹ́yìn tí wọ́n dárí ìsìn láti bọ́ sínú ọdún tuntun.
Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Èrèlè 2025 ní 13:34:54
Aarẹ orilẹede Rwanda ati Congo yoo peju sibi ipade alaafia ajọ awọn orilẹede to wa lẹkun naa ti yoo waye ni orilẹede Tanzania lọjọ Ẹti.
Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Èrèlè 2025 ní 09:55:41
Ijọba ipinlẹ Ogun sọ pe igbesẹ idaduro Olorile-Ifo, Oba Abdulsemiu Ogunjobi, ko ṣẹyin awọn ọrọ kobakungbe ati aṣemaṣe ti kabiyesi naa ṣe ninu fidio to lu ori ayelujara pa.
Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Èrèlè 2025 ní 09:39:13
Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera àgbáyé, World Health Organization, WHO ní èèyàn mílíọ̀nù kan ó lé ọgọ́rùn-ún kan ló máa ń ní àìsàn jẹjẹrẹ nílẹ̀ Áfíríkà ní ọdọọdún àti pé èèyàn 700,000 ló máa ń ba lọ.
Ọjọ́ Ìsẹ́gun, 4 Oṣù Èrèlè 2025 ní 06:35:37
Ṣaaju ninu atẹjade kan ti aarẹ ẹgbẹ naa, Joe Ajaero, buwọlu ni NLC ti kede igbesẹ yii nibi ipade igbimọ alaṣẹ ẹgbẹ naa to waye l’ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kinni yii niluu Abuja.
Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Èrèlè 2025 ní 17:53:07
Ohun ti a ri gbọ ni pe awọn eeyan ilu ti kesi ijọba pe ko gbe baale ilu sipo Oba gẹgẹ bii Olojudo ti ilu Ido Ayegunle, ko si ma yan olori tuntun fun wọn.
Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Èrèlè 2025 ní 15:38:32
O kere tan, awọn araalu gbọdọ ṣe oriṣi inṣọransi ti oloyinbo n pe ni Third-party, gẹgẹ bi aṣẹ ọga ọlọpaa Naijiria
Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Èrèlè 2025 ní 13:51:03
Kò dín ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin (700) èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà, táwọn bíi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn mìíràn sì tún farapa gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, UN àti ìjọba Congo ṣe sọ.
Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Èrèlè 2025 ní 13:22:38
Lọdun 2024 ni ijọba ti kọkọ fi kun owo ina lorilẹede NAijiria
Ọjọ́ Ajé, 3 Oṣù Èrèlè 2025 ní 09:45:58
Bi o tilẹ jẹ pe itan ni ijakadi naa, o ti di ayẹyẹ ọdọọdun ni ilu Offa bayii.
Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Èrèlè 2025 ní 11:26:33
Ní nǹkan bíi ọ̀sẹ̀ mélòó kan sẹ́yìn ni ọ̀rọ̀ ìdásílẹ̀ ìgbìmọ̀ Sharia ti ń fa awuyewuye káàkiri ilẹ̀ Yorùbá.
Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Èrèlè 2025 ní 18:15:31
Iṣẹlẹ naa waye ni ijọba ibilẹ Odigbo ni irọlẹ ọjọ Satide ọjọ kinni oṣe keji ọdun 2025.
Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Èrèlè 2025 ní 10:40:16
Àṣẹ náà ní ìdílé Lagbua ló máa jẹ́ ìdílé karùn-ún, tí yóò sì máa jẹ ọba kẹ́yìn lásìkò tí ìyànsípò ọba yóò bá wáyé.
Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Èrèlè 2025 ní 09:50:57
Gẹgẹ ti atẹjade kan ti ileeṣẹ Dangote fi sita, lati ọjọ Abamẹta ọjọ kinni oṣu Keji ọdun yii ni adinku ti ba owo epo bẹntiroolu.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Èrèlè 2025 ní 17:46:40
Ọpọ awọn eeyan yii lo ni igbagbọ pe o ṣeeṣe ki wọn ma fi wọn sọwọ pada si orilẹede Naijiria titi wọ asiko ti Aarẹ Trump yoo fi yi ipinnu rẹ pada.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Èrèlè 2025 ní 08:23:29
Lateef Adedimeji, nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tó ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn The Punch ní òun mọ̀ọ́mọ̀ kó ipá ẹlẹ́kún nígbà tí òun bẹ̀rẹ̀ eré láti lè ní ohun ìdánimọ̀ kan pàtó tí àwọn èèyàn yóò mọ òun mọ́.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Èrèlè 2025 ní 08:40:41
Ninu ifọrọwerọ kan ti Ọjọgbọn Pate to tun wa fun ọrọ igbayegbadun araalu, ṣe pẹlu BBC lo ti sọ pe bawọn kan tiẹ n japa, awọn iṣi mi-in tun wa ti yoo rọpo wọn.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Èrèlè 2025 ní 12:08:25
Ọkọ̀ òfurufú náà ló ń gbé ọmọ tó ń ṣe àárẹ̀, ìyá rẹ̀ àtàwọn òṣìṣẹ́ ìrìnnà òfurufú náà ló wà nínú rẹ̀ lásìkò tí ìjákulẹ̀ náà wáyé.
Ọjọ́ Ẹtì, 31 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 13:50:48
Alaga ajọ CAN ni Gomina Seyi Makinde ti fi erongba rẹ han lori ọrọ Shari’ah pe iwe ofin orilẹede Naijiria nikan loun mọ nipinle Oyo.
Ọjọ́ Ẹtì, 31 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 15:37:43
Adajọ paṣẹ pe oniduuro naa gbọdọ fi iwe irinna rẹ silẹ fun kootu, o si gbọdọ bura fun kootu pẹlu.
Ọjọ́ Ẹtì, 31 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 12:32:46
Iroyin naa sọ pe awọn ọmọ Naijiria lo wa nipo keji ninu awọn to n japa ju.
Ọjọ́ Àìkú, 2 Oṣù Èrèlè 2025 ní 08:30:54
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtàn to pọ̀ lóde kò fi bẹ́ẹ̀ dárúkọ rẹ̀, nítorí pé ìtàn àtẹnudẹ̀nu ló pọ̀jù nínú ìtàn orile-ede Naijiria, ọ̀pọ̀ sí ló máa ń sọ ìtàn bí ẹni pé ọkùnrin nìkan ló n jẹ Ooni Ife.
Ọjọ́ Àbámẹ́ta, 1 Oṣù Èrèlè 2025 ní 10:31:30
Ní ọjọ́rú, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù Kìíní, ọdún 2025 ni Adájọ́ AO Ayoola ti ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé bí ìjọba ṣe yọ Ọba Famodun kò tọ̀nà rárá.
Ọjọ́ Ẹtì, 31 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 15:23:24
Olabisi Ayeni, to jẹ igbakeji agbẹnusọ ileeṣẹ naa lo fi ikede ọhun sita.
Ọjọ́ Ẹtì, 31 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 14:25:31
Junjie jẹ ọkan ninu ọpọ eeyan ti BBC ba sọrọ lẹyin ti wọn dero ile iwosan aarun ọpọlọ lẹyin ti wọn se ifẹhonuhan tako ijọba.
Ọjọ́ Ẹtì, 31 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 09:18:12
Agba osere Kristiẹni ni Korede Are nigba aye rẹ, to si ti kopa ninu ọpọ sinima Kristiẹni, ki ọlọjọ to de.
Ọjọ́ Ẹtì, 31 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 10:51:16
Ninu ọrọ ọga agba NOA, o ni owo ti ijọba apapọ fun mọlẹbi Oloogbe naa ki i ṣe owo ọya fun awọn iṣẹ to ṣe nigba aye rẹ, bi ko ṣe lati ṣe iranlọwọ fun ẹbi rẹ nitori ipa rere to ko lorilẹede yii.
Ọjọ́ Ẹtì, 31 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 07:10:59
Ọdun 2023 ni oloogbe naa dana sun iwe mimọ awọn Musulumi niwaju mọṣalaṣi nla Stockholm Central Mosque.
Ọjọ́bọ, 30 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 10:10:48
BBC bá ìdílé kan pàdé tó ń gbẹ́ sàárè fún ọpọ̀ ọdún láì gba owó oṣù tàbí owó ọ̀yà.
Ọjọ́bọ, 30 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 11:50:36
Bisi Akande ní òun sọ fún Tinubu pé ìran Yorùbá ló fẹ́ ṣe ààrẹ fún, pé kìí ṣe nítorí ara rẹ̀ ni àwọn ṣe ní kó díje.
Ọjọ́bọ, 30 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 06:12:25
Isẹlẹ naa lo waye lasiko ti baalu akero naa fẹ ba lopopona baalu kẹtalelọgbọn, ti iwadi si ti n lọ nipa ohun to fa isẹlẹ naa.
Ọjọ́bọ, 30 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 10:44:06
Gẹgẹ bii atẹjade kan to wa lati ọfiisi adari oṣiṣẹ nipinlẹ Oyo ṣe sọ, wiwọ asọ oke lọ si ọfiisi ni gbogbo Ọjọgbọ jẹ ọna lati se igbelarugẹ aṣa ati iṣe awọn eeyan ipinlẹ Oyo.
Ọjọ́bọ, 30 Oṣù Ṣẹ́rẹ́ 2025 ní 16:49:11
Sultan Sokoto fi kun pe ofin orilẹede Naijiria ti wọn kọ lọdun 1999 faye gba ile ẹjọ Sharia gẹgẹ bo ṣe faye gba ile ẹjọ ijọba to n da si aawọ laarin araalu.